Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 13:6-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Gẹgẹ bi a ti bọ́ wọn, bẹ̃ni nwọn yó; nwọn yó, nwọn si gbe ọkàn wọn ga; nitorina ni nwọn ṣe gbagbe mi.

7. Nitorina li emi o ṣe dabi kiniun si wọn; emi o si ma ṣọ wọn bi ẹkùn li ẹ̀ba ọ̀na.

8. Emi o pade wọn bi beari ti a gbà li ọ̀mọ, emi o si fà àwọn ọkàn wọn ya, nibẹ̀ ni emi o si jẹ wọn run bi kiniun, ẹranko igbẹ ni yio fà wọn ya.

9. Israeli, iwọ ti pa ara rẹ run, niti pe iwọ wà lodi si emi, irànlọwọ rẹ.

10. Nibo li ọba rẹ gbe wà nisisiyi ninu gbogbo ilu rẹ, ti o le gbà ọ? ati awọn onidajọ rẹ, niti awọn ti iwọ wipe; Fun mi li ọba ati awọn ọmọ-alade.

11. Emi fun ọ li ọba ni ibinu mi, mo si mu u kuro ni irúnu mi.

12. A dì aiṣedẽde Efraimu; ẹ̀ṣẹ rẹ̀ pamọ.

13. Irora obinrin ti nrọbi yio de si i: alaigbọn ọmọ li on; nitori on kò duro li akokò si ibi ijade ọmọ.

14. Emi o rà wọn padà lọwọ agbara isà-okú; Emi o rà wọn padà lọwọ ikú; Ikú, ajàkalẹ arùn rẹ dà? Isà-okú, iparun rẹ dà? ironupiwàda yio pamọ kuro loju mi.

15. Bi on tilẹ ṣe eleso ninu awọn arakunrin rẹ̀, afẹfẹ́ ilà-õrùn kan yio de, afẹ̃fẹ́ Oluwa yio ti aginjù wá, orisun rẹ̀ yio si gbẹ, ati oju isun rẹ̀ li a o mu gbẹ: on o bà ohun elò daradara gbogbo jẹ.

Ka pipe ipin Hos 13