Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 13:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI Efraimu sọ̀rọ, ìwarìri ni; o gbe ara rẹ̀ ga ni Israeli; ṣugbọn nigbati o ṣẹ̀ ninu Baali, o kú.

2. Nisisiyi, nwọn si dá ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ, nwọn si ti fi fàdakà wọn ṣe ere didà fun ara wọn, ati òriṣa ìmọ wọn: iṣẹ oniṣọnà ni gbogbo rẹ̀; nwọn wi niti wọn pe, Jẹ ki awọn enia ti nrubọ fi ẹnu kò awọn ọmọ malu li ẹnu.

3. Nitorina ni nwọn o ṣe dabi kũkũ owurọ̀, ati bi irì owurọ̀ ti nkọja lọ, bi iyangbò ti a ti ọwọ́ ijì gbá kuro ninu ilẹ ipakà, ati bi ẹ̃fin ti ijade kuro ninu ile ẹ̃fin.

4. Ṣugbọn emi li Oluwa Ọlọrun rẹ lati ilẹ Egipti wá, iwọ kì yio si mọ̀ ọlọrun kan bikòṣe emi: nitori kò si olugbàla kan lẹhìn mi.

5. Emi ti mọ̀ ọ li aginjù, ni ilẹ ti o pongbẹ.

6. Gẹgẹ bi a ti bọ́ wọn, bẹ̃ni nwọn yó; nwọn yó, nwọn si gbe ọkàn wọn ga; nitorina ni nwọn ṣe gbagbe mi.

Ka pipe ipin Hos 13