Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 12:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EFRAIMU njẹ afẹfẹ́, o si ntọ̀ afẹfẹ́ ila-õrun lẹhìn: o nmu eke ati iparun pọ̀ si i lojojumọ; nwọn si ba awọn ara Assiria da majẹmu, nwọn si nrù ororo lọ si Egipti.

2. Oluwa ni ẹjọ kan ba Juda rò pẹlu, yio si jẹ Jakobu ni iyà gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀; gẹgẹ bi iṣe rẹ̀ ni yio san padà fun u.

3. O di arakunrin rẹ̀ mu ni gigisẹ̀ ni inu, ati nipa ipá rẹ̀ o ni agbara pẹlu Ọlọrun.

4. Nitõtọ, o ni agbara lori angeli, o si bori: o sọkun, o si bẹ̀bẹ lọdọ rẹ̀: o ri i ni Beteli, nibẹ̀ li o gbe ba wa sọ̀rọ;

5. Ani Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun; Oluwa ni iranti rẹ̀.

6. Nitorina, iwọ yipadà si Ọlọrun rẹ: pa ãnu ati idajọ mọ, ki o si ma duro de Ọlọrun rẹ nigbagbogbo.

7. Kenaani ni, iwọ̀n ẹtàn mbẹ li ọwọ́ rẹ̀: o fẹ lati ninilara.

Ka pipe ipin Hos 12