Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hag 1:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọdun keji Dariusi ọba, li oṣù kẹfa, li ọjọ ekini oṣù na, ọ̀rọ Oluwa wá, nipa ọwọ Hagai woli, sọdọ Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, bãlẹ Juda, ati sọdọ Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa, wipe,

2. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Awọn enia wọnyi nsọ pe, Akokò kò ti ide, akokò ti a ba fi kọ́ ile Oluwa.

3. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa wá nipa Hagai woli, wipe,

4. Akokò ha ni fun nyin, ẹnyin, lati ma gbe ile ọṣọ nyin, ṣugbọn ile yi wà li ahoro?

5. Njẹ nisisiyi bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Ẹ kiyesi ọ̀na nyin.

6. Ẹnyin ti fọ́n irugbin pupọ̀, ẹ si mu diẹ wá ile; ẹnyin njẹ, ṣugbọn ẹnyin kò yo: ẹnyin nmu, ṣugbọn kò tẹ nyin lọrun; ẹnyin mbora, ṣugbọn kò si ẹniti o gboná; ẹniti o si ngbowo ọ̀ya ńgbà a sinu ajadi àpo.

7. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: Ẹ kiyesi ọ̀na nyin.

8. Ẹ gùn ori oke-nla lọ, ẹ si mu igi wá, ki ẹ si kọ́ ile na; inu mi yio si dùn si i, a o si yìn mi logo, li Oluwa wi.

9. Ẹnyin tí nreti ọ̀pọ, ṣugbọn kiyesi i, diẹ ni; nigbati ẹnyin si mu u wá ile, mo si fẹ ẹ danù. Nitori kini? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Nitori ti ile mi ti o dahoro; ti olukuluku nyin si nsare fun ile ara rẹ̀.

10. Nitorina ni a ṣe dá ìri ọrun duro lori nyin, a si da eso ilẹ duro.

11. Mo si ti pè ọdá sori ilẹ, ati sori oke-nla, ati sori ọkà ati sori ọti-waini titún, ati sori ororo, ati sori ohun ti ilẹ mu jade, ati sori enia, ati sori ẹran, ati sori gbogbo iṣẹ ọwọ ẹni.

Ka pipe ipin Hag 1