Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hab 2:6-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Gbogbo awọn wọnyi kì yio ma pa owe si i, ti nwọn o si ma kọ orin owe si i, wipe, Egbe ni fun ẹniti nmu ohun ti kì iṣe tirẹ̀ pọ̀ si i! yio ti pẹ to? ati fun ẹniti ndi ẹrẹ̀ ilọnilọwọgbà ru ara rẹ̀.

7. Awọn ti o yọ ọ lẹnu, kì yio ha dide lojiji? awọn ti o wahalà rẹ kì yio ha ji? iwọ kì yio ha si di ikogun fun wọn?

8. Nitori iwọ ti kó orilẹ-ède pupọ̀, gbogbo iyokù awọn enia na ni yio kó ọ; nitori ẹjẹ̀ enia, ati ìwa-ipá ilẹ na, ti ilu na, ati ti gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀.

9. Egbe ni fun ẹniti njẹ erè ijẹkujẹ si ile rẹ̀, ki o lè ba gbe itẹ́ rẹ̀ ka ibi giga, ki a lè ba gbà a silẹ kuro lọwọ ibi!

10. Iwọ ti gbìmọ itìju si ile rẹ, nipa kike enia pupọ̀ kuro, o si ti ṣẹ̀ si ọkàn rẹ.

11. Nitoriti okuta yio kigbe lati inu ogiri wá, ati igi-idábu lati inu òpo wá yio si da a lohùn.

12. Egbe ni fun ẹniti o fi ẹjẹ̀ kọ ilu, ti o si fi aiṣedede tẹ̀ ilu nla do.

Ka pipe ipin Hab 2