Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gẹn 50:8-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ati gbogbo awọn ara ile Josefu, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn ara ile baba rẹ̀: kìki awọn ọmọ wẹ́wẹ wọn, ati ọwọ́-ẹran wọn, ati ọwọ́-malu wọn, ni nwọn fi silẹ ni ilẹ Goṣeni.

9. Ati kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin si bá a goke lọ: ẹgbẹ nlanla si ni ẹgbẹ na.

10. Nwọn si dé ibi ilẹ ipakà Atadi, ti o wà li oke Jordani, nibẹ̀ ni nwọn si gbé fi ohùn rére ẹkún nlanla ṣọ̀fọ rẹ̀: o si ṣọ̀fọ fun baba rẹ̀ li ọjọ́ meje.

11. Nigbati awọn ara ilẹ na, awọn ara Kenaani, si ri ọ̀fọ na ni ibi ilẹ ipakà Atadi, nwọn wipe, Ọ̀fọ nla li eyi fun awọn ara Egipti: nitorina ni nwọn ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Abel-misraimu, ti o wà loke odò Jordani.

12. Awọn ọmọ rẹ̀ si ṣe bi o ti fi aṣẹ fun wọn:

13. Nitori ti awọn ọmọ rẹ̀ mú u lọ si ilẹ Kenaani, nwọn si sin i ninu ihò oko Makpela, ti Abrahamu rà pẹlu oko fun iní ilẹ isinku, lọwọ Efroni ara Hitti, niwaju Mamre.

14. Josefu si pada wá si Egipti, on ati awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ti o bá a goke lọ lati sin baba rẹ̀, lẹhin ti o ti sin baba rẹ̀ tán.

15. Nigbati awọn arakunrin Josefu ri pe baba wọn kú tán, nwọn wipe, Bọya Josefu yio korira wa, yio si gbẹsan gbogbo ibi ti a ti ṣe si i lara wa.

16. Nwọn si rán onṣẹ tọ̀ Josefu lọ wipe, Baba rẹ ti paṣẹ ki o tó kú pe,

17. Bayi ni ki ẹnyin wi fun Josefu pe, Njẹ emi bẹ̀ ọ, dari irekọja ati ẹ̀ṣẹ awọn arakunrin rẹ jì wọn, nitori ibi ti nwọn ṣe si ọ. Njẹ nisisiyi, awa bẹ̀ ọ, dari irekọja awọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọn. Josefu si sọkun nigbati nwọn sọ fun u.

18. Awọn arakunrin rẹ̀ si lọ pẹlu, nwọn wolẹ niwaju rẹ̀: nwọn si wipe, Wò o, iranṣẹ rẹ li awa iṣe.

19. Josefu si wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: emi ha wà ni ipò Ọlọrun?

20. Ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, ibi li ẹnyin rò si mi; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọ si rere, lati mu u ṣẹ, bi o ti ri loni lati gbà ọ̀pọlọpọ enia là.

21. Njẹ nisisiyi, ẹ má bẹ̀ru: emi o bọ́ nyin, ati awọn ọmọ wẹrẹ nyin. O si tù wọn ninu, o si sọ̀rọ rere fun wọn.

Ka pipe ipin Gẹn 50