Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Est 9:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Njẹ li oṣù kejila, eyini ni oṣù Adari, li ọjọ kẹtala rẹ̀, ti ofin ọba ati aṣẹ rẹ̀ sunmọle lati mu u ṣẹ, li ọjọ ti awọn ọta awọn Ju ti rò pe, awọn o bori wọn, (bi o tilẹ ti jẹ pe, ati yi i pada pe, ki awọn Ju ki o bori awọn ti o korira wọn;)

2. Awọn Ju kó ara wọn jọ ninu ilu wọn ninu gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, lati gbe ọwọ le iru awọn ti o nwá ifarapa wọn: ẹnikẹni kò si le kò wọn loju; nitori ẹ̀ru wọn bà gbogbo enia.

3. Gbogbo awọn olori ìgberiko, ati awọn bãlẹ, ati awọn onidajọ, ati awọn ti nṣe iṣẹ ọba, ràn awọn Ju lọwọ, nitori ẹ̀ru Mordekai bà wọn.

4. Nitori Mordekai tobi ni ile ọba, okiki rẹ̀ si kàn ja gbogbo ìgberiko: nitori ọkunrin yi Mordekai ntobi siwaju ati siwaju.

5. Bayi ni awọn Ju a fi idà ṣá gbogbo awọn ọta wọn pa, ni pipa ati piparun, nwọn si ṣe awọn ọta ti o korira wọn bi nwọn ti fẹ.

6. Ati ni Ṣuṣani ãfin awọn Ju pa ẹ̃dẹgbẹta ọkunrin run.

7. Ati Farṣandata, ati Dalfoni, ati Aspata,

8. Ati Porata, ati Adalia, ati Aridata,

9. Ati Farmaṣta, ati Arisai, ati Aridai, ati Faisata,

10. Awọn ọmọ Hamani, ọmọ Medata, mẹwẹwa, ọta awọn Ju ni nwọn pa; ṣugbọn nwọn kò fi ọwọ kàn nkan wọn.

11. Li ọjọ na a mu iye awọn ti a pa ni Ṣuṣani ãfin wá siwaju ọba.

Ka pipe ipin Est 9