Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Est 8:12-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Li ọjọ kanṣoṣo ni gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, li ọjọ kẹtala, oṣù kejila ti iṣe oṣù Adari.

13. Ọ̀ran inu iwe na ni lati paṣẹ ni gbogbo ìgberiko lati kede rẹ̀ fun gbogbo enia, ki awọn Ju ki o le mura de ọjọ na, lati gbẹsan ara wọn lara awọn ọta wọn.

14. Bẹ̃ni awọn ojiṣẹ́ ti nwọn gun ẹṣin yiyara ati ibãka jade lọ, nitori aṣẹ ọba, nwọn yara, nwọn sare. A si pa aṣẹ yi ni Ṣuṣani ãfin.

15. Mordekai si jade kuro niwaju ọba, ninu aṣọ ọba, alaro ati funfun, ati ade wura nla, ati ẹ̀wu okùn ọ̀gbọ kikuná, ati elese aluko; ayọ̀ ati inu didùn si wà ni ilu Ṣuṣani.

16. Awọn Ju si ni imọlẹ, ati inu didùn, ati ayọ̀ ati ọlá.

17. Ati ni olukulùku ìgberiko, ati ni olukuluku ilu nibikibi ti ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀ ba de, awọn Ju ni ayọ̀ ati inu-didùn, àse, ati ọjọ rere. Ọ̀pọlọpọ awọn enia ilẹ na si di enia Juda; nitori ẹ̀ru awọn Ju ba wọn.

Ka pipe ipin Est 8