Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Est 8:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ni ijọ na ni Ahaswerusi ọba fi ile Hamani ọta awọn Ju, jìn Esteri, ayaba; Mordekai si wá siwaju ọba; nitori Esteri ti sọ bi o ti ri si on.

2. Ọba si bọ́ oruka rẹ̀, ti o ti gbà lọwọ Hamani, o si fi i fun Mordekai. Esteri si fi Mordekai ṣe olori ile Hamani.

3. Esteri si tun sọ niwaju ọba, o wolẹ lẹba ẹsẹ̀ rẹ̀, o si fi omijé bẹ̀ ẹ pe, ki o mu buburu Hamani, ara Agagi kuro, ati ete ti o ti pa si awọn Ju.

4. Nigbana ni ọba nà ọpá-alade wura si Esteri. Bẹ̃ni Esteri dide, o si duro niwaju ọba.

5. O si wi pe, bi o ba wù ọba, bi mo ba si ri ore-ọfẹ loju rẹ̀, ti nkan na ba si tọ́ loju ọba, bi mo ba si wù ọba, jẹ ki a kọwe lati yí iwe ete Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi nì pada, ti o ti kọ lati pa awọn Ju run, ti o wà ni gbogbo ìgberiko ọba.

6. Nitori pe, emi ti ṣe le ri ibi ti yio wá ba awọn enia mi? tabi emi ti ṣe le ri iparun awọn ibatan mi?

7. Nigbana ni Ahaswerusi ọba wi fun Esteri ayaba, ati fun Mordekai ara Juda na pe, Sa wò o, emi ti fi ile Hamani fun Esteri; on ni nwọn si ti so rọ̀ lori igi, nitoripe o ti gbe ọwọ le awọn Ju.

8. Ẹnyin kọwe ẹ̀wẹ li orukọ ọba, nitori awọn Ju bi ẹnyin ti fẹ́, ki ẹ si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀: nitori iwe ti a ba fi orukọ ọba kọ, ti a ba si fi òruka ọba ṣe edidi, ẹnikan kò le yi i pada.

9. Nigbana li a si pè awọn akọwe ọba li akokò na ni oṣù kẹta, eyini ni oṣù Sifani, li ọjọ kẹtalelogun rẹ̀; a si kọ ọ gẹgẹ bi Mordekai ti paṣẹ si awọn Ju, ati si awọn bãlẹ, ati awọn onidajọ, ati olori awọn ìgberiko metadilãdoje, si olukulùku ìgberiko gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati si olukulùku enia gẹgẹ bi ède wọn ati si awọn Ju gẹgẹ bi ikọwe wọn, ati gẹgẹ bi ède wọn.

10. Orukọ Ahaswerusi ọba li a fi kọ ọ, a si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀; o si fi iwe wọnni rán awọn ojiṣẹ lori ẹṣin, ti o gùn ẹṣin yiyara, ani ibãka, ọmọ awọn abo ẹṣin.

11. Ninu eyiti ọba fi aṣẹ fun gbogbo awọn Ju, ti o wà ni ilu gbogbo, lati kó ara wọn jọ, ati lati duro gbà ẹmi ara wọn là, lati parun, lati pa, ati lati mu ki gbogbo agbara awọn enia, ati ìgberiko na, ti o ba fẹ kọlu wọn, pẹlu awọn ọmọ wẹwẹ ati awọn obinrin ki o ṣegbe; ki nwọn ki o si kó ìni wọn fun ara wọn,

12. Li ọjọ kanṣoṣo ni gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, li ọjọ kẹtala, oṣù kejila ti iṣe oṣù Adari.

13. Ọ̀ran inu iwe na ni lati paṣẹ ni gbogbo ìgberiko lati kede rẹ̀ fun gbogbo enia, ki awọn Ju ki o le mura de ọjọ na, lati gbẹsan ara wọn lara awọn ọta wọn.

Ka pipe ipin Est 8