Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Est 2:2-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Nigbana ni awọn ọmọ-ọdọ ọba, ti nṣe iranṣẹ fun u, wi pe, jẹ ki a wá awọn wundia ti o li ẹwà fun ọba.

3. Ki ọba ki o si yàn olori ni gbogbo ìgberiko ijọba rẹ̀, ki nwọn ki o le ṣà awọn wundia ti o li ẹwà jọ wá si Ṣuṣani ãfin, si ile awọn obinrin, si ọdọ Hegai, ìwẹfa ọba olutọju awọn obinrin; ki a si fi elo ìwẹnumọ́ wọn fun wọn:

4. Ki wundia na ti o ba wù ọba ki o jẹ ayaba ni ipò Faṣti. Nkan na si dara loju ọba, o si ṣe bẹ̃.

5. Ọkunrin ara Juda kan wà ni Ṣuṣani ãfin, orukọ ẹniti ijẹ Mordekai, ọmọ Jairi, ọmọ Ṣemei, ọmọ Kisi, ara Benjamini.

6. Ẹniti a ti mu lọ lati Jerusalemu pẹlu ìgbekun ti a kó lọ pẹlu Jekoniah, ọba Juda, ti Nebukadnessari, ọba Babeli ti kó lọ.

7. On li o si tọ́ Hadassa dagba, eyini ni Esteri, ọmọbinrin arakunrin baba rẹ̀: nitori kò ni baba, bẹ̃ni kò si ni iya, wundia na si li ẹwà, o si dara lati wò; ẹniti, nigbati baba ati iya rẹ̀ ti kú tan, Mordekai mu u ṣe ọmọbinrin ontikalarẹ̀,

8. O si ṣe, nigbati a gbọ́ ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀, nigbati a si ṣà ọ̀pọlọpọ wundia jọ si Ṣuṣani ãfin, si ọwọ Hegai, a si mu Esteri wá si ile ọba pẹlu si ọwọ Hegai, olutọju awọn obinrin.

9. Wundia na si wù u, o si ri ojurere gbà lọdọ rẹ̀; o si yara fi elo ìwẹnumọ́ rẹ̀ fun u, ati ipin onjẹ ti o jẹ tirẹ̀, ati obinrin meje ti a yàn fun u lati ile ọba wá: on si ṣi i lọ ati awọn wundia rẹ̀ si ibi ti o dara jù ni ile awọn obinrin.

10. Esteri kò ti ifi awọn enia rẹ̀, tabi awọn ibatan rẹ̀ hàn; nitori Mordekai paṣẹ fun u ki o máṣe fi hàn.

11. Mordekai a si ma rìn lojojumọ niwaju àgbala ile awọn obinrin, lati mọ̀ alafia Esteri, ati bi yio ti ri fun u.

Ka pipe ipin Est 2