orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Est 10 Yorùbá Bibeli (YCE)

Títóbi Ahasu-erusi ati Modekai

1. AHASWERUSI ọba si fi owo ọba le ilẹ fun gbogbo ilẹ, ati gbogbo erekùṣu okun.

2. Ati gbogbo iṣe agbara rẹ̀, ati ti ipa rẹ̀, ati ìrohin titobi Mordekai, bi ọba ti sọ ọ di nla, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Media ati Persia?

3. Nitori Mordekai ara Juda li o ṣe igbakeji Ahaswerusi ọba, o si tobi ninu awọn Ju, o si ṣe itẹwọgbà lọdọ ọ̀pọlọpọ ninu awọn arakunrin rẹ̀, o nwá ire awọn enia rẹ̀, o si nsọ̀rọ alafia fun gbogbo awọn iru-ọmọ rẹ̀.