Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esr 7:9-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Nitoripe lati ọjọ kini oṣu ekini li o bẹrẹ si igòke lati Babiloni wá, ati li ọjọ ikini oṣu karun li o de Jerusalemu, gẹgẹ bi ọwọ rere Ọlọrun rẹ̀ ti o wà lara rẹ̀.

10. Nitori Esra ti mura tan li ọkàn rẹ̀ lati ma wá ofin Oluwa, ati lati ṣe e, ati lati ma kọ́ni li ofin ati idajọ ni Israeli.

11. Eyi si ni atunkọ iwe na ti Artasasta ọba fi fun Esra alufa, akọwe, ani akọwe ọ̀rọ ofin Oluwa, ati ti aṣẹ rẹ̀ fun Israeli.

12. Artasasta, ọba awọn ọba, si Esra alufa, akọwe pipé ti ofin Ọlọrun ọrun, alafia:

13. Mo paṣẹ pe, ki gbogbo enia ninu awọn enia Israeli, ati ninu awọn alufa rẹ̀ ati awọn ọmọ Lefi, ninu ijọba mi, ẹniti o ba fẹ nipa ifẹ inu ara wọn lati gòkẹ lọ si Jerusalemu, ki nwọn ma ba ọ lọ.

14. Niwọn bi a ti rán ọ lọ lati iwaju ọba lọ ati ti awọn ìgbimọ rẹ̀ mejeje, lati wadi ọ̀ran ti Juda ati Jerusalemu gẹgẹ bi ofin Ọlọrun rẹ ti mbẹ li ọwọ rẹ;

15. Ati lati ko fàdaka ati wura, ti ọba ati awọn ìgbimọ fi tinutinu fi fun Ọlọrun Israeli, ibugbe ẹniti o wà ni Jerusalemu.

Ka pipe ipin Esr 7