Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esr 7:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ lẹhin nkan wọnyi, ni ijọba Artasasta ọba Persia, Esra ọmọ Seraiah, ọmọ Asariah, ọmọ Hilkiah,

2. Ọmọ Ṣallumu, ọmọ Sadoku, ọmọ Ahitubu,

3. Ọmọ Amariah, ọmọ Asariah, ọmọ Meraiotu,

4. Ọmọ Serahiah, ọmọ Ussi, ọmọ Bukki,

5. Ọmọ Abiṣua, ọmọ Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni olori alufa:

6. Esra yi li o gòke lati Babiloni wá; o si jẹ ayáwọ́-akọwe ninu ofin Mose, ti Oluwa Ọlọrun Israeli fi fun ni: ọba si fun u li ohun gbogbo ti o bère, gẹgẹ bi ọwọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ti wà lara rẹ̀.

7. Ati ninu awọn ọmọ Israeli, ati ninu awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati awọn akọrin, ati awọn adèna, pẹlu awọn Netinimu si goke wá si Jerusalemu li ọdun keje Artasasta ọba.

8. On si wá si Jerusalemu li oṣu karun, eyi ni ọdun keje ọba.

9. Nitoripe lati ọjọ kini oṣu ekini li o bẹrẹ si igòke lati Babiloni wá, ati li ọjọ ikini oṣu karun li o de Jerusalemu, gẹgẹ bi ọwọ rere Ọlọrun rẹ̀ ti o wà lara rẹ̀.

10. Nitori Esra ti mura tan li ọkàn rẹ̀ lati ma wá ofin Oluwa, ati lati ṣe e, ati lati ma kọ́ni li ofin ati idajọ ni Israeli.

11. Eyi si ni atunkọ iwe na ti Artasasta ọba fi fun Esra alufa, akọwe, ani akọwe ọ̀rọ ofin Oluwa, ati ti aṣẹ rẹ̀ fun Israeli.

Ka pipe ipin Esr 7