Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esr 3:4-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Nwọn si pa àse agọ mọ pẹlu, gẹgẹ bi a ti kọ ọ, nwọn si rú ẹbọ sisun ojojumọ pẹlu nipa iye ti a pa li aṣẹ, gẹgẹ bi isin ojojumọ;

5. Lẹhin na nwọn si ru ẹbọ sisun igbagbogbo ati ti oṣu titun, ati ti gbogbo ajọ Oluwa, ti a si yà si mimọ́, ati ti olukuluku ti o fi tinu-tinu ru ẹbọ atinuwa si Oluwa.

6. Lati ọjọ ikini oṣu keje ni nwọn bẹ̀rẹ lati ma rú ẹbọ sisun si Oluwa. Ṣugbọn a kò ti ifi ipilẹ tempili Oluwa lelẹ.

7. Nwọn si fi owo fun awọn ọmọle pẹlu, ati fun awọn gbẹna-gbẹna, pẹlu onjẹ, ati ohun mimu, ati ororo, fun awọn ara Sidoni, ati fun awọn ara Tire, lati mu igi kedari ti Lebanoni wá si okun Joppa, gẹgẹ bi aṣẹ ti nwọn gbà lati ọwọ Kirusi ọba Persia.

Ka pipe ipin Esr 3