32. Awọn ọmọ Harimu, ọrindinirinwo.
33. Awọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono, ọrindilẹgbẹrin o le marun,
34. Awọn ọmọ Jeriko, ọtadinirinwo o le marun.
35. Awọn ọmọ Sanaa, egbejidilogun o le ọgbọn.
36. Awọn alufa; awọn ọmọ Jedaiah, ti idile Jeṣua, ogúndilẹgbẹrun o din meje.
37. Awọn ọmọ Immeri, ãdọtalelẹgbẹrun o le meji.
38. Awọn ọmọ Paṣuri, ojilelẹgbẹfa o le meje.
39. Awọn ọmọ Harimu, ẹgbẹrun o le mẹtadilogun.
40. Awọn ọmọ Lefi: awọn ọmọ Jeṣua ati Kadmieli ti awọn ọmọ Hodafiah, mẹrinlelãdọrin.
41. Awọn akọrin: awọn ọmọ Asafu, mejidilãdoje.
42. Awọn ọmọ awọn adena: awọn ọmọ Ṣalumu, awọn ọmọ Ateri, awọn ọmọ Talmoni, awọn ọmọ Akkubu, awọn ọmọ Hatita, awọn ọmọ Ṣobai, gbogbo wọn jẹ, mọkandilogoje.
43. Awọn Netinimu: awọn ọmọ Siha, awọn ọmọ Hasufa, awọn ọmọ Tabbaoti.