Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esr 2:27-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Awọn ọmọ Mikmasi, mejilelọgọfa.

28. Awọn enia Beteli ati Ai, igba o le mẹtalelogun.

29. Awọn ọmọ Nebo, mejilelãdọta.

30. Awọn ọmọ Magbiṣi mẹrindilọgọjọ.

31. Awọn ọmọ Elamu ekeji, ãdọtalelẹgbẹfa o le mẹrin.

32. Awọn ọmọ Harimu, ọrindinirinwo.

33. Awọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono, ọrindilẹgbẹrin o le marun,

34. Awọn ọmọ Jeriko, ọtadinirinwo o le marun.

35. Awọn ọmọ Sanaa, egbejidilogun o le ọgbọn.

36. Awọn alufa; awọn ọmọ Jedaiah, ti idile Jeṣua, ogúndilẹgbẹrun o din meje.

37. Awọn ọmọ Immeri, ãdọtalelẹgbẹrun o le meji.

38. Awọn ọmọ Paṣuri, ojilelẹgbẹfa o le meje.

39. Awọn ọmọ Harimu, ẹgbẹrun o le mẹtadilogun.

40. Awọn ọmọ Lefi: awọn ọmọ Jeṣua ati Kadmieli ti awọn ọmọ Hodafiah, mẹrinlelãdọrin.

41. Awọn akọrin: awọn ọmọ Asafu, mejidilãdoje.

42. Awọn ọmọ awọn adena: awọn ọmọ Ṣalumu, awọn ọmọ Ateri, awọn ọmọ Talmoni, awọn ọmọ Akkubu, awọn ọmọ Hatita, awọn ọmọ Ṣobai, gbogbo wọn jẹ, mọkandilogoje.

43. Awọn Netinimu: awọn ọmọ Siha, awọn ọmọ Hasufa, awọn ọmọ Tabbaoti.

Ka pipe ipin Esr 2