Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 7:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

2. Iwọ ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi pẹlu si ile Israeli; Opin, opin de sori igun mẹrẹrin ilẹ.

3. Opin de si ọ wayi, emi o si rán ibinu mi sori rẹ, emi o si da ọ lẹjọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ; emi o si san gbogbo irira rẹ pada si ọ lori.

4. Oju mi kì yio si dasi, bẹ̃li emi kì yio ṣãnu: ṣugbọn emi o san ọ̀na rẹ pada si ọ lori, ati irira rẹ yio wà li ãrin rẹ: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.

5. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; ibi kan, ibi kanṣoṣo, kiye si i, o de.

6. Opin de, opin de: o jí si ọ; kiye si i, o de.

7. Ilẹ mọ́ ọ, iwọ ẹniti ngbe ilẹ na: akokò na de, ọjọ wahala sunmọ tosí; kì isi ṣe ariwo awọn oke-nla.

8. Nisisiyi li emi o dà ikannu mi si ọ lori, emi o si mu ibinu mi ṣẹ si ọ lori: emi o si dá ọ lẹjọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, emi o si san fun ọ nitori gbogbo irira rẹ.

9. Oju mi kì yio si dasi, bẹ̃li emi kì yio ṣãnu: emi o si san fun ọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, ati irira rẹ ti mbẹ lãrin rẹ; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa ti nkọlu.

10. Kiye si i ọjọ na, kiyesi i, o de: ilẹ ti mọ́; ọpá ti tanná, irera ti rudi.

11. Iwa-ipa ti dide di ọpa ìwa buburu: ọkan ninu wọn kì yio kù, tabi ninu ọ̀pọlọpọ wọn, tabi ninu ohun kan wọn, bẹ̃ni kì yio si ipohùnreré ẹkun fun wọn.

Ka pipe ipin Esek 7