Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 47:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si mu mi padà wá si ibi ilẹkùn ile na; si kiyesi i, omi ntù jade lati abẹ iloro ile na nihà ila-õrun: nitori iwaju ile na wà ni ila-õrun, omi si nwalẹ lati abẹ apa ọtun ile na, ni gusu pẹpẹ.

2. O si mu mi jade ni ọ̀na ẹnu-ọ̀na ihà ariwa, o si mu mi yi wá ọ̀na ode si ẹnu-ọ̀na ode ni ọ̀na ti o kọjusi ila-õrun; si kiyesi i, omi ṣàn jade lati ihà ọtun.

3. Nigbati ọkunrin na jade sihà ila-õrun, pẹlu okùn kan lọwọ rẹ̀, o si wọ̀n ẹgbẹrun igbọnwọ, o si mu mi là omi na ja; omi na si de kókosẹ̀.

4. O tun wọ̀n ẹgbẹrun, o si mu mi là omi na ja; omi na si de ẽkun. O si wọ̀n ẹgbẹrun, o si mu mi là a ja; omi si de ẹgbẹ́.

5. O si wọ̀n ẹgbẹrun; odò ti nkò le wọ́: nitori omi ti kún, omi ilúwẹ, odò ti kò ṣe rekọja.

6. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, Iwọ ri yi? O si mu mi wá, o si mu mi pada wá si bèbe odò na.

7. Nigbati mo pada, si kiyesi i, igi pupọ̀pupọ̀ wà ni ihà ihin ati ni ihà ọhun li eti odò na.

8. O si wi fun mi pe, Omi wọnyi ntú jade sihà ilẹ ila-õrun, nwọn si nsọkalẹ lọ si pẹ̀tẹlẹ, nwọn si wọ̀ okun lọ: nigbati a si mu wọn wọ̀ inu okun, a si mu omi wọn lara dá.

9. Yio si ṣe pe, ohunkohun ti o ba wà lãye ti nrakò, nibikibi ti odò mejeji ba de, yio wà lãye: ọ̀pọlọpọ ẹja yio si de, nitori omi wọnyi yio de ibẹ̀: a o si mu wọn lara dá; ohun gbogbo yio si yè nibikibi ti odò na ba de.

10. Yio si ṣe pe, Awọn apẹja yio duro lori rẹ̀ lati Engedi titi de Eneglaimu; nwọn o jẹ ibi lati nà àwọn si; ẹja wọn o dabi iru wọn, bi ẹja okun-nla, lọpọlọpọ.

Ka pipe ipin Esek 47