Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 42:13-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. O si wi fun mi pe, Awọn yará ariwa ati awọn yará gusu, ti o wà niwaju ibiti a yà sọtọ̀, awọn ni yará mimọ́, nibiti awọn alufa ti nsunmọ Oluwa yio ma jẹ ohun mimọ́ julọ: nibẹ̀ ni nwọn o ma gbe ohun mimọ́ julọ kà, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja; nitori ibẹ̀ jẹ mimọ́.

14. Nigbati awọn alufa ba wọ̀ ibẹ̀, nwọn kì yio si kuro ni ibi mimọ́ si agbala ode, ṣugbọn nibẹ nibiti nwọn gbe nṣiṣẹ ni nwọn o fi ẹwù wọn si; nitori nwọn jẹ mimọ́; nwọn o si wọ̀ ẹwù miran, nwọn o si sunmọ nkan wọnni ti o jẹ́ ti enia.

15. Nigbati o si ti wọ̀n ile ti inu tan, o mu mi wá sihà ilẹkùn ti o kọju si ọ̀na ila-õrun, o si wọ̀n yika.

16. O fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa ila-õrun, ẹ̃dẹgbẹta ije, nipa ije iwọ̀nlẹ yika.

17. O si fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa ariwa, ẹ̃dẹgbẹta ije yika.

18. O si fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa gusu, ẹ̃dẹgbẹta ije.

19. O yipadà si ọ̀na iwọ-õrun, o si fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ọ, ẹ̃dẹgbẹta ije.

20. O wọ̀n ọ nihà mẹrẹrin: o ni ogiri kan yi i ka, ẹ̃dẹgbẹta ije ni gigùn, ati ẹ̃dẹgbẹta ni ibú, lati pàla lãrin ibi mimọ́ ati ibi aimọ́.

Ka pipe ipin Esek 42