Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 42:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si mu mi wá si agbala ode, li ọ̀na apa ariwa: o si mu mi wá si yará ti o kọju si ibi ti a yà sọtọ̀, ti o si kọju si ile lọna ariwa.

2. Niwaju, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn ni ilẹkun ariwa, ati ibú rẹ̀ ãdọta igbọnwọ.

3. Niwaju, ogún igbọnwọ ti o wà fun agbalá ti inu, ati niwaju itẹle ti o wà fun agbalá ti ode; ibujoko oke ti o kọju si ibujoko-oke wà ni orule mẹta.

4. Ati niwaju awọn yará ni irìn igbọnwọ mẹwa ni ibú ninu, ọ̀na igbọnwọ kan; ilẹkùn wọn si wà nihà ariwa.

5. Ati awọn yará oke kuru jù; nitori ibujoko ti awọn yará isalẹ ati yará ãrin yọ siwaju wọnyi ti ile.

6. Nitori nwọn jẹ olorule mẹta, ṣugbọn nwọn kò ni ọwọ̀n bi ọwọ̀n agbalá: nitorina a fasẹhin kuro ninu yará isalẹ ati kuro ninu yará ãrin lati ilẹ wá.

Ka pipe ipin Esek 42