Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 41:4-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Bẹ̃ li o si wọ̀n gigùn rẹ̀, ogún igbọnwọ; ati ibú rẹ̀, ogún igbọnwọ, niwaju tempili: o si wi fun mi pe, Eyi ni ibi mimọ́ julọ.

5. O si wọ̀n ogiri ile na, igbọnwọ mẹfa; ati ibú yàrá-ihà gbogbo igbọnwọ mẹrin, yi ile na ka nihà gbogbo.

6. Ati awọn yará-ihà, ọkan lori ekeji jẹ mẹta, nigba ọgbọ̀n: nwọn si wọ̀ inu ogiri ti ile awọn yará-ihà na yika, ki nwọn ba le di ara wọn mu, nitori kò si idimú ninu ogiri ile na.

7. A si ṣe e gborò, o si lọ yika loke awọn yará ihà: nitori ogiri ile na lọ loke-loke yi ile na ka: nitorina ibú ile na wà loke, bẹ̃ni iyará isalẹ yọ si toke lãrin.

8. Emi si ri giga ile na yika: ipilẹ awọn yará-ẹ̀gbẹ́ na si jẹ ije kikun kan ti igbọnwọ mẹfa ni gigun.

9. Ibú ogiri na, ti yará-ẹ̀gbẹ́ lode, jẹ igbọnwọ marun: ati eyi ti o kù ni ibi yará-ẹ̀gbẹ́ ti mbẹ ninu.

10. Ati lãrin yará na, ogún igbọnwọ ni gbigborò, yi ile na ka ni ihà gbogbo.

11. Ati ilẹkùn awọn yará-ẹ̀gbẹ́ na mbẹ li ọ̀na ibi ti o kù, ilẹkùn kan li ọ̀na ariwa, ati ilẹkùn kan ni gusu: ati ibú ibẹ̀ na ti o kù, jẹ igbọnwọ marun yika.

12. Ati ile ti o wà niwaju eyiti a yà sọtọ̀ ni igun ọ̀na iwọ-õrun, jẹ ãdọrin igbọnwọ ni gbigborò; ogiri ile na si jẹ igbọnwọ marun ni ibú yika, ati gigùn rẹ̀, ãdọrun igbọnwọ.

13. O si wọ̀n ile na, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn; ati ibi ti a yà sọtọ̀, ati ile na, pẹlu ogiri wọn, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn.

14. Ati ibú oju ile na, ati ti ibi ti a yà sọtọ̀ nihà ila-õrun ọgọrun igbọnwọ.

15. O si wọ̀n gigun ile na ti o kọju si ibiti a yà sọtọ̀ ti mbẹ lẹhin rẹ̀, ati ibujoko-oke ni ihà kan ati nihà miran, ọgọrún igbọnwọ, pẹlu tempeli inu, ati iloro agbalá na;

16. Awọn iloro, ati ferese toro, ati ibujoko oke yika lori ile olorule mẹta wọn, ti o wà niwaju iloro na, li a fi igi tẹ́ yika, ati lati ilẹ de oke ferese, a si bò awọn ferese na;

17. Si ti oke ilẹkun ani titi de ile ti inu, ati ti ode, ati lara ogiri niha gbogbo tinu tode ni wiwọ̀n.

18. Kerubu ati igi ọpẹ li a si fi ṣe e, igi ọpẹ kan si mbẹ lãrin kerubu ati kerubu: kerubu kọkan si ni oju meji;

19. Oju enia kan si wà nihà ibi igi ọpe li apa kan, ati oju ẹgbọ̀rọ kiniun kan si wà nihà ibi igi ọpẹ li apa keji: a ṣe e yi ile na ka niha gbogbo.

20. Lati ilẹ titi fi de okè ilẹkùn, ni a ṣe kerubu ati igi ọpẹ si, ati lara ogiri tempili na.

21. Awọn opó ilẹkùn tempili na jẹ igun mẹrin lọgbọgba: ati iwaju ibi mimọ́ irí ọkan bi irí ekeji.

22. Pẹpẹ igi na jẹ igbọnwọ mẹta ni giga, gigùn rẹ̀ igbọnwọ meji; ati igun rẹ̀, ati gigùn rẹ̀, ati awọn ogiri rẹ̀ jẹ ti igi: o si wi fun mi pe, Eyi ni tabili ti mbẹ niwaju Oluwa.

Ka pipe ipin Esek 41