Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 40:6-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nigbana li o wá si ẹnu-ọ̀na ti o kọju si ọ̀na ila-õrun, o si gùn oke atẹ̀gun na lọ, o si wọ̀n iloro ẹnu ọ̀na, ti o jẹ ije kan ni ibú; ati iloro miran ti ẹnu-ọ̀na na, ti o jẹ ije kan ni ibú.

7. Yará kékèké si jẹ ije kan ni gigùn, ati ije kan ni ibú; ati lãrin yará kékèké igbọnwọ marun; àtẹwọ ẹnu-ọ̀na lẹba iloro ẹnu-ọ̀na ti inu si jẹ ije kan.

8. O si wọ̀n iloro ẹnu-ọ̀na ti inu, ije kan.

9. O si wọ̀n iloro ẹnu-ọ̀na, igbọnwọ mẹjọ; ati atẹrigba rẹ̀, igbọnwọ meji-meji; iloro ti ẹnu-ọ̀na na si mbẹ ninu.

10. Ati yará kékèké ẹnu-ọ̀na ti ọ̀na ila-õrun jẹ mẹta nihà ìhin, ati mẹta nihà ọhún; awọn mẹtẹta jẹ ìwọn kanna: awọn atẹrigba na jẹ ìwọn kanna niha ìhin ati niha ọhún.

11. O si wọ̀n ibu abawọle ẹnu-ọ̀na na, igbọnwọ mẹwa; ati gigùn ẹnu-ọ̀na na, igbọnwọ mẹtala.

12. Àye ti si mbẹ niwaju awọn yará kékèké na jẹ igbọnwọ kan nihà ìhin, àye na si jẹ igbọnwọ kan nihá ọhún; awọn yará kékèké na si jẹ igbọnwọ mẹfa nihà ìhin, ati igbọnwọ mẹfa niha ọhún.

Ka pipe ipin Esek 40