Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 40:5-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Si kiye si i, ogiri kan mbẹ lode ile na yika, ije iwọ̀nlẹ kan si mbẹ lọwọ ọkunrin na, igbọnwọ mẹfa, nipa igbọnwọ ati ibú atẹlẹwọ kan: o si wọ̀n ibú ile na, ije kan; ati giga rẹ̀, ije kan.

6. Nigbana li o wá si ẹnu-ọ̀na ti o kọju si ọ̀na ila-õrun, o si gùn oke atẹ̀gun na lọ, o si wọ̀n iloro ẹnu ọ̀na, ti o jẹ ije kan ni ibú; ati iloro miran ti ẹnu-ọ̀na na, ti o jẹ ije kan ni ibú.

7. Yará kékèké si jẹ ije kan ni gigùn, ati ije kan ni ibú; ati lãrin yará kékèké igbọnwọ marun; àtẹwọ ẹnu-ọ̀na lẹba iloro ẹnu-ọ̀na ti inu si jẹ ije kan.

8. O si wọ̀n iloro ẹnu-ọ̀na ti inu, ije kan.

9. O si wọ̀n iloro ẹnu-ọ̀na, igbọnwọ mẹjọ; ati atẹrigba rẹ̀, igbọnwọ meji-meji; iloro ti ẹnu-ọ̀na na si mbẹ ninu.

10. Ati yará kékèké ẹnu-ọ̀na ti ọ̀na ila-õrun jẹ mẹta nihà ìhin, ati mẹta nihà ọhún; awọn mẹtẹta jẹ ìwọn kanna: awọn atẹrigba na jẹ ìwọn kanna niha ìhin ati niha ọhún.

11. O si wọ̀n ibu abawọle ẹnu-ọ̀na na, igbọnwọ mẹwa; ati gigùn ẹnu-ọ̀na na, igbọnwọ mẹtala.

12. Àye ti si mbẹ niwaju awọn yará kékèké na jẹ igbọnwọ kan nihà ìhin, àye na si jẹ igbọnwọ kan nihá ọhún; awọn yará kékèké na si jẹ igbọnwọ mẹfa nihà ìhin, ati igbọnwọ mẹfa niha ọhún.

Ka pipe ipin Esek 40