Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 40:43-49 Yorùbá Bibeli (YCE)

43. Ati ninu ni ìwọ ẹlẹnu meji, oníbu atẹlẹwọ kan, ti a kàn mọ ọ yika: ati lori awọn tabili na ni ẹran ọrẹ gbe wà.

44. Ati lode ẹnu-ọ̀na ti inu ni yará awọn akọrin gbe wà, ninu agbala ti inu, ti mbẹ ni ihà ẹnu-ọ̀na ariwa; oju wọn si wà li ọ̀na gusu: ọkan ni iha ẹnu-ọ̀na ila-õrun, oju eyiti mbẹ li ọ̀na ariwa.

45. O si wi fun mi pe, Yàrá yi, ti oju rẹ̀ mbẹ li ọ̀na gusu, ni fun awọn alufa, awọn olutọjú iṣọ ile na.

46. Yará ti oju rẹ̀ mbẹ li ọ̀na ariwa, ni fun awọn alufa, awọn olutọjú iṣọ pẹpẹ na; awọn wọnyi li awọn ọmọ Sadoku ninu awọn ọmọ Lefi, ti nwọn ima sunmọ Oluwa lati ṣe iranṣẹ fun u.

47. O si wọ̀n agbalá na, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn, ọgọrun igbọnwọ ni ibú, igun mẹrin lọgbọgba; ati pẹpẹ ti mbẹ niwaju ile na.

48. O si mu mi wá si iloro ile na, o si wọ̀n opo iloro na, igbọnwọ marun nihà ìhin, ati igbọnwọ marun nihà ọ̀hun: ibu ẹnu-ọ̀na na si jẹ igbọnwọ mẹta nihà ìhin, ati igbọnwọ mẹta nihà ọ̀hun.

49. Gigùn iloro na jẹ ogún igbọnwọ, ibú rẹ̀ igbọnwọ mọkànla; o si mu mi wá si atẹ̀gun ti nwọn ifi ba gokè rẹ̀: ọwọ̀n pupọ̀ si mbẹ nihà ibi atẹrigbà, ọkan nihin, ati ọkan lọhun.

Ka pipe ipin Esek 40