Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 36:26-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Emi o fi ọkàn titun fun nyin pẹlu, ẹmi titun li emi o fi sinu nyin, emi o si mu ọkàn okuta kuro lara nyin, emi o si fi ọkàn ẹran fun nyin.

27. Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, emi o si mu ki ẹ ma rìn ninu aṣẹ mi, ẹnyin o pa idajọ mi mọ, ẹ o si ma ṣe wọn.

28. Ẹnyin o si ma gbe ilẹ ti emi fi fun awọn baba nyin; ẹnyin o si ma jẹ enia mi, emi o si ma jẹ Ọlọrun nyin.

29. Emi o si gbà nyin là kuro ninu aimọ́ nyin gbogbo: emi o si pè ọkà wá, emi o si mu u pọ̀ si i, emi kì yio si mu ìyan wá ba nyin.

30. Emi o si sọ eso-igi di pupọ̀, ati ibísi oko, ki ẹ má bà gbà ẹ̀gan ìyan mọ lãrin awọn keferi.

31. Nigbana li ẹnyin o ranti ọ̀na buburu nyin, ati iṣe nyin ti kò dara, ẹ o si sú ara nyin li oju ara nyin fun aiṣedẽde nyin, ati fun irira nyin.

Ka pipe ipin Esek 36