Eyi ni ohùn-rére, nwọn o si pohùnrére rẹ̀: awọn ọmọbinrin awọn orilẹ-ède yio pohùnrére rẹ̀: nwọn o pohùnrére nitori rẹ̀, ani fun Egipti, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.