Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 30:16-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Emi o si gbe iná kalẹ ni Egipti, Sini yio ni irora nla, a o si fà No ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, Nofi yio si ni ipọnju lojojumọ.

17. Awọn ọdọmọkunrin Afeni ati Pibeseti yio ti ipa idà ṣubu: ati awọn wọnyi yio lọ si igbèkun.

18. Ọjọ yio si ṣõkun ni Tehafnehesi, nigbati emi bá dá àjaga ọrùn Egipti nibẹ: ọṣọ́ agbara rẹ̀ yio tán ninu rẹ̀: bi o ṣe tirẹ̀ ni, ikũkũ yio bò on, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin yio lọ si igbèkun.

19. Bayi li emi o mu idajọ ṣẹ ni Egipti: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

20. O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣù kini, li ọjọ keje oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,

21. Ọmọ enia, emi ti ṣẹ apá Farao ọba Egipti; si kiyesi i, a kì yio dì i ki o ba le san, bẹ̃ni a kì yio fi igi si i lati dì i ki o ba lagbara lati di idà mu.

22. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; kiyesi i, emi dojukọ Farao ọba Egipti, emi o si ṣẹ́ apá rẹ̀, eyi ti o le, ati eyiti o ṣẹ́; emi o si jẹ ki idà bọ́ kuro li ọwọ́ rẹ̀.

23. Emi o si tú awọn ara Egipti ká sãrin awọn orilẹ-ède, emi o si tú wọn ká sãrin ilẹ.

24. Emi o si mu apá ọba Babiloni le, emi o si fi idà mi si ọwọ́ rẹ̀: ṣugbọn emi o ṣẹ́ apá Farao, yio si ma kerora niwaju rẹ bi ikérora ọkunrin ti a ṣá li aṣápa.

25. Ṣugbọn emi o mu apá ọba Babiloni le, apá Farao yio si rọ; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o ba fi idà mi si ọwọ́ ọba Babiloni, ki o le ba nà a sori ilẹ Egipti.

26. Emi o si tú awọn ara Egipti ká sãrin awọn orilẹ-ède, emi o si tú wọn ká sãrin awọn ilẹ; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Ka pipe ipin Esek 30