Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 3:3-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, mu ki ikùn rẹ jẹ, ki o si fi iká-iwé yi ti emi fi fun ọ kún inu rẹ. Nigbana ni mo jẹ ẹ, o si dabi oyin li ẹnu ni didùn.

4. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, Lọ, tọ̀ ile Israeli lọ ki o si fi ọ̀rọ mi ba wọn sọrọ.

5. Nitori a kò ran ọ si enia ède ajeji ati sisọrọ, ṣugbọn si ile Israeli.

6. Ki iṣe si ọ̀pọlọpọ enia ède ajeji, ati ède sisọrọ, ọ̀rọ ẹniti iwọ kò le gbọ́. Nitotọ emi iba rán ọ si wọn, nwọn iba gbọ́ tirẹ.

7. Ṣugbọn ile Israeli kò ni gbọ́ tirẹ; nitori ti nwọn kò fẹ gbọ́ ti emi: nitori alafojudi ati ọlọkàn lile ni gbogbo ile Israeli.

8. Kiyesi i, mo ti sọ oju rẹ di lile si oju wọn, ati iwaju rẹ di lile si iwaju wọn.

9. Bi okuta diamondi ti o le ju okuta ibọn ni mo ṣe iwaju rẹ: máṣe bẹ̀ru wọn, bẹ̃ni ki o máṣe fòya oju wọn, bi nwọn tilẹ jẹ ọlọ̀tẹ ile.

10. Pẹlupẹlu o wi fun mi pe, Ọmọ enia, gba gbogbo ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ si ọkàn rẹ, si fi eti rẹ gbọ́ wọn.

11. Si lọ, tọ̀ awọn ti igbekùn lọ, awọn ọmọ enia rẹ, si ba wọn sọ̀rọ, ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; bi nwọn o gbọ́, tabi bi nwọn o kọ̀.

12. Ẹmi si gbe mi soke, mo si gbọ́ ohùn iró nla lẹhin mi, nwipe, Ibukun ni fun ogo Oluwa lati ipò rẹ̀ wá.

13. Mo si gbọ́ ariwo iyẹ́ awọn ẹ̀da alãye, ti o kàn ara wọn, ati ariwo awọn kẹkẹ́ ti o wà pẹlu wọn, ati ariwo iró nla.

14. Bẹ̃ni ẹmi na gbe mi soke, o si mu mi kuro, mo si lọ ni ibinujẹ, ati ninu gbigbona ọkàn mi; ṣugbọn ọwọ́ Oluwa le lara mi.

15. Nigbana ni mo tọ̀ awọn ti igbekùn ti Telabibi lọ, ti nwọn ngbe ẹba odò Kebari, mo si joko nibiti nwọn joko, ẹnu si yà mi bi mo ti wà lãrin wọn ni ijọ meje.

16. O si di igbati o ṣe li opin ijọ meje, ọ̀rọ Oluwa wá sọdọ mi, wipe:

17. Ọmọ enia, mo ti fi iwọ ṣe oluṣọ́ fun ile Israeli, nitorina gbọ́ ọ̀rọ li ẹnu mi, si kilọ fun wọn lati ọdọ mi wá.

Ka pipe ipin Esek 3