Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 29:12-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Emi o si sọ ilẹ Egipti di ahoro li ãrin awọn ilẹ ti o di ahoro, ati ilu rẹ̀ yio si di ahoro li ãrin awọn ilu ti o di ahoro li ogoji ọdun: emi o si tú awọn ara Egipti ká sãrin gbogbo orilẹ-ède, emi o si tú wọn ká sãrin gbogbo ilẹ.

13. Ṣugbọn bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Lẹhin ogoji ọdun li emi o ko awọn ara Egipti jọ lati ọdọ awọn enia nibiti a ti tú wọn ká si:

14. Emi o si tun mu igbèkun Egipti pada bọ̀, emi o si mu wọn pada si ilẹ Patrosi, si ilẹ ibí wọn, nwọn o si wà nibẹ bi ijọba ti a rẹ̀ silẹ.

15. Yio si jẹ ijọba ti o rẹ̀lẹ jù ninu awọn ijọba; bẹ̃ni kì yio si gbe ara rẹ̀ ga mọ́ sori awọn orilẹ-ède: nitori emi o dín wọn kù, ti nwọn kì yio fi ṣe olori awọn orilẹ-ède mọ́.

16. Kì yio si jẹ igbẹkẹle fun ile Israeli mọ́, ti o mu aiṣedẽde wọn wá si iranti, nigbati nwọn o ba wò wọn: ṣugbọn nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun.

17. O si ṣe li ọdun kẹtadilọgbọ̀n, li oṣù ikini, li ọjọ ikini oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,

Ka pipe ipin Esek 29