Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 29:10-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nitorina, kiyesi i, emi dojukọ ọ, mo si dojukọ odò rẹ, emi o si sọ ilẹ Egipti di ahoro patapata, lati Migdoli lọ de Siene ati titi de ẹkùn Etiopia.

11. Ẹsẹ enia kì yio kọja li ãrin rẹ̀, bẹ̃ni ẹsẹ ẹrankẹran kì yio kọja li ãrin rẹ̀, bẹ̃ni a kì yio tẹ̀ ẹ dó li ogoji ọdun.

12. Emi o si sọ ilẹ Egipti di ahoro li ãrin awọn ilẹ ti o di ahoro, ati ilu rẹ̀ yio si di ahoro li ãrin awọn ilu ti o di ahoro li ogoji ọdun: emi o si tú awọn ara Egipti ká sãrin gbogbo orilẹ-ède, emi o si tú wọn ká sãrin gbogbo ilẹ.

13. Ṣugbọn bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Lẹhin ogoji ọdun li emi o ko awọn ara Egipti jọ lati ọdọ awọn enia nibiti a ti tú wọn ká si:

14. Emi o si tun mu igbèkun Egipti pada bọ̀, emi o si mu wọn pada si ilẹ Patrosi, si ilẹ ibí wọn, nwọn o si wà nibẹ bi ijọba ti a rẹ̀ silẹ.

15. Yio si jẹ ijọba ti o rẹ̀lẹ jù ninu awọn ijọba; bẹ̃ni kì yio si gbe ara rẹ̀ ga mọ́ sori awọn orilẹ-ède: nitori emi o dín wọn kù, ti nwọn kì yio fi ṣe olori awọn orilẹ-ède mọ́.

16. Kì yio si jẹ igbẹkẹle fun ile Israeli mọ́, ti o mu aiṣedẽde wọn wá si iranti, nigbati nwọn o ba wò wọn: ṣugbọn nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun.

Ka pipe ipin Esek 29