Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 29:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọdun kẹwa, li oṣù kẹwa, li ọjọ kejila oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,

2. Ọmọ enia, kọ oju rẹ si Farao ọba Egipti, si sọtẹlẹ si i, ati si gbogbo Egipti:

3. Sọ̀rọ, ki o si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi doju kọ ọ; Farao ọba Egipti, dragoni nla ti o dubulẹ li ãrin awọn odò rẹ̀, eyiti o ti wipe, Ti emi li odò mi, emi li o si ti wà a fun ara mi.

4. Ṣugbọn emi o fi ìwọ kọ́ ọ li ẹ̀rẹkẹ́, emi o si jẹ ki ẹja odò rẹ ki o lẹ mọ́ ipẹ́ rẹ, emi o si mu ọ kuro li ãrin odò rẹ, ati gbogbo ẹja odò rẹ yio lẹ mọ́ ipẹ́ rẹ.

5. Emi o si sọ ọ nù si aginjù, iwọ ati gbogbo ẹja odò rẹ: iwọ o ṣubu ni gbangba oko: a kì yio si kó ọ jọ, bẹ̃li a kì yio si ṣà ọ jọ: emi ti fi ọ ṣe onjẹ fun awọn ẹranko igbẹ́, ati fun awọn ẹiyẹ oju ọrun.

6. Gbogbo awọn olugbé Egipti yio mọ̀ pe emi li Oluwa, nitori nwọn ti jẹ́ ọpá ìye fun ile Israeli.

Ka pipe ipin Esek 29