Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 29:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọdun kẹwa, li oṣù kẹwa, li ọjọ kejila oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,

2. Ọmọ enia, kọ oju rẹ si Farao ọba Egipti, si sọtẹlẹ si i, ati si gbogbo Egipti:

3. Sọ̀rọ, ki o si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi doju kọ ọ; Farao ọba Egipti, dragoni nla ti o dubulẹ li ãrin awọn odò rẹ̀, eyiti o ti wipe, Ti emi li odò mi, emi li o si ti wà a fun ara mi.

4. Ṣugbọn emi o fi ìwọ kọ́ ọ li ẹ̀rẹkẹ́, emi o si jẹ ki ẹja odò rẹ ki o lẹ mọ́ ipẹ́ rẹ, emi o si mu ọ kuro li ãrin odò rẹ, ati gbogbo ẹja odò rẹ yio lẹ mọ́ ipẹ́ rẹ.

5. Emi o si sọ ọ nù si aginjù, iwọ ati gbogbo ẹja odò rẹ: iwọ o ṣubu ni gbangba oko: a kì yio si kó ọ jọ, bẹ̃li a kì yio si ṣà ọ jọ: emi ti fi ọ ṣe onjẹ fun awọn ẹranko igbẹ́, ati fun awọn ẹiyẹ oju ọrun.

6. Gbogbo awọn olugbé Egipti yio mọ̀ pe emi li Oluwa, nitori nwọn ti jẹ́ ọpá ìye fun ile Israeli.

7. Nigbati nwọn di ọ lọwọ mu, iwọ fọ́, o si ya gbogbo èjiká wọn: nigbati nwọn si fi ara tì ọ, iwọ ṣẹ́, o si mu gbogbo ẹgbẹ́ wọn gbọ̀n.

8. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Kiyesi i, emi o mu idà kan wá sori rẹ, ti yio ké enia ati ẹranko kuro ninu rẹ.

9. Ilẹ Egipti yio si di aginjù yio si di ahoro; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa: nitori ti o ti wipe, Odò na temi ni, emi li o si ti wà a.

10. Nitorina, kiyesi i, emi dojukọ ọ, mo si dojukọ odò rẹ, emi o si sọ ilẹ Egipti di ahoro patapata, lati Migdoli lọ de Siene ati titi de ẹkùn Etiopia.

Ka pipe ipin Esek 29