Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 28:7-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Kiyesi i, nitorina emi o mu alejo wá ba ọ, ẹlẹ̀ru ninu awọn orilẹ-ède: nwọn o si fà idà wọn yọ si ẹwà ọgbọ́n rẹ, nwọn o si bà didán rẹ jẹ.

8. Nwọn o mu ọ sọkalẹ wá sinu ihò, iwọ o si kú ikú awọn ti a pa li ãrin okun.

9. Iwọ ha le sọ sibẹ niwaju ẹni ti npa ọ, pe, Emi li Ọlọrun? ṣugbọn enia ni iwọ, o kì yio si jẹ Ọlọrun, lọwọ ẹniti npa ọ.

10. Iwọ o kú ikú awọn alaikọlà lọwọ awọn alejo: nitori emi li o ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi.

11. Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe,

12. Ọmọ enia, pohùnréré sori ọba Tire, ki o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ fi edidi dí iye na, o kún fun ọgbọ́n, o si pé li ẹwà.

13. Iwọ ti wà ni Edeni ọgbà Ọlọrun; oniruru okuta iyebiye ni ibora rẹ, sardiu, topasi, ati diamondi, berili, oniki, ati jasperi, safire, emeraldi, ati karbunkili, ati wura: iṣẹ ìlu rẹ ati ti fère rẹ li a pèse ninu rẹ li ọjọ ti a dá ọ.

14. Iwọ ni kerubu ti a nà ti o si bò; emi si ti gbe ọ kalẹ: iwọ wà lori oke mimọ́ Ọlọrun; iwọ ti rìn soke rìn sodò lãrin okuta iná.

15. Iwọ pé li ọnà rẹ lati ọjọ ti a ti dá ọ, titi a fi ri aiṣedẽde ninu rẹ.

16. Nitori ọ̀pọlọpọ òwo rẹ, nwọn ti fi iwà-ipa kún ãrin rẹ, iwọ si ti ṣẹ̀: nitorina li emi o ṣe sọ ọ nù bi ohun ailọ̀wọ kuro li oke Ọlọrun: emi o si pa ọ run, iwọ kerubu ti o bò, kuro lãrin okuta iná.

17. Ọkàn rẹ gbe soke nitori ẹwà rẹ, o ti bà ọgbọ́n rẹ jẹ nitori dídan rẹ; emi o bì ọ lulẹ, emi o gbe ọ kalẹ niwaju awọn ọba, ki nwọn ba le wò ọ.

18. Iwọ ti bà ibi mimọ́ rẹ jẹ nipa ọ̀pọlọpọ aiṣedẽde rẹ, nipa aiṣedẽde òwo rẹ; nitorina emi o mu iná jade lati ãrin rẹ wá, yio jó ọ run, emi o si sọ ọ di ẽru lori ilẹ loju gbogbo awọn ti o wò ọ:

Ka pipe ipin Esek 28