Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 27:28-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Awọn ilẹ àgbègbe yio mì nitori iró igbe awọn atọkọ̀ rẹ.

29. Gbogbo awọn alajẹ̀, awọn atukọ̀, ati awọn atọ́kọ̀ okun yio sọkalẹ kuro ninu ọkọ̀ wọn, nwọn o duro lori ilẹ.

30. Nwọn o si jẹ ki a gbọ́ ohùn wọn si ọ, nwọn o si kigbe kikoro, nwọn o si kù ekuru sori ara wọn, nwọn o si yi ara wọn ninu ẽru:

31. Nwọn o si fari wọn patapata fun ọ, nwọn o si fi aṣọ-àpo di ara wọn, nwọn o si sọkun fun ọ ni ikorò aiya, pẹlu ohùnrére ẹkun kikorò.

32. Ati ninu arò wọn ni nwọn o si pohùnrére ẹkún fun ọ, nwọn o si pohùnrére ẹkún sori rẹ, wipe, Ta li o dabi Tire, eyiti a parun li ãrin okun?

33. Nigbati ọjà-tità rẹ ti okun jade wá, iwọ tẹ́ orilẹ-ède pupọ lọrun; iwọ fi ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ rẹ, ati ọjà rẹ, sọ awọn ọba aiye di ọlọrọ̀.

34. Nisisiyi ti okun fọ́ ọ bajẹ̀ ninu ibú omi, nitorina òwo rẹ, ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ li ãrin rẹ, li o ṣubu.

35. Ẹnu yio yà gbogbo awọn olugbe erekuṣu wọnni si ọ, awọn ọba wọn yio si dijì, iyọnu yio yọ li oju wọn.

36. Awọn oniṣòwo lãrin awọn orilẹ-ède yio dún bi ejò si ọ; iwọ o si jẹ ẹ̀ru, iwọ kì yio si si mọ́ lailai.

Ka pipe ipin Esek 27