Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 27:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,

2. Nisisiyi, iwọ ọmọ enia, pohunrere ẹkun fun Tire;

3. Ki o si wi fun Tire pe, Iwọ ti a tẹ̀do si ẹnu-ọ̀na okun, oniṣòwo awọn orilẹ-ède fun ọ̀pọlọpọ erekùṣu, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ Tire, iwọ ti wipe, emi pé li ẹwà.

4. Àlà rẹ wà li ãrin okun, awọn ọ̀mọle rẹ ti mu ẹwà rẹ pé.

5. Nwọn ti fi apako firi ti Seniri kàn gbogbo ọkọ̀ rẹ, nwọn ti mu kedari ti Lebanoni wá lati fi ṣe opó ọkọ̀ fun ọ.

6. Ninu igi oaku ti Baṣani ni nwọn ti fi gbẹ́ àjẹ rẹ; ijoko rẹ ni nwọn fi ehin-erin ṣe pelu igi boksi lati erekuṣu Kittimu wá.

Ka pipe ipin Esek 27