Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 26:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣu ikini, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,

2. Ọmọ enia, nitoriti Tire ti sọ̀rọ si Jerusalemu, pe, Aha, a fọ́ eyiti iṣe bode awọn orilẹ-ède: a yi i pada si mi, emi o di kikún, on di ahoro:

3. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; kiyesi i, mo doju kọ ọ, iwọ Tire, emi o si jẹ ki orilẹ-ède pupọ dide si ọ, gẹgẹ bi okun ti igbé ríru rẹ̀ soke.

4. Nwọn o si wó odi Tire lulẹ, nwọn o si wó ile iṣọ́ rẹ̀ lulẹ; emi o si há erùpẹ rẹ̀ kuro lara rẹ̀, emi o si ṣe e bi ori apata.

5. Yio jẹ ibi ninà awọ̀n si lãrin okun: nitori mo ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi: yio si di ikogun fun awọn orilẹ-ède.

6. Ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ ti o wà li oko, li a o fi idà pa; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

7. Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu Nebukadnessari ọba Babiloni, ọba awọn ọba, wá si Tire, lati ariwa, pẹlu ẹṣin, ati kẹkẹ́ ogun, ati ẹlẹṣin, ati ẹgbẹ́, ati enia pupọ.

8. Yio fi idà pa awọn ọmọbinrin rẹ li oko: yio si kọ kũkũ tì ọ, yio si mọ odi tì ọ, yio si gbe apata soke si ọ.

Ka pipe ipin Esek 26