Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 26:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣu ikini, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,

2. Ọmọ enia, nitoriti Tire ti sọ̀rọ si Jerusalemu, pe, Aha, a fọ́ eyiti iṣe bode awọn orilẹ-ède: a yi i pada si mi, emi o di kikún, on di ahoro:

3. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; kiyesi i, mo doju kọ ọ, iwọ Tire, emi o si jẹ ki orilẹ-ède pupọ dide si ọ, gẹgẹ bi okun ti igbé ríru rẹ̀ soke.

4. Nwọn o si wó odi Tire lulẹ, nwọn o si wó ile iṣọ́ rẹ̀ lulẹ; emi o si há erùpẹ rẹ̀ kuro lara rẹ̀, emi o si ṣe e bi ori apata.

5. Yio jẹ ibi ninà awọ̀n si lãrin okun: nitori mo ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi: yio si di ikogun fun awọn orilẹ-ède.

6. Ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ ti o wà li oko, li a o fi idà pa; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Ka pipe ipin Esek 26