1. Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, li ọdun kẹsan, li oṣu kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣu, wipe,
2. Ọmọ enia, iwọ kọ orukọ ọjọ na, ani ọjọ kanna yi: ọba Babiloni doju kọ Jerusalemu li ọjọ kanna yi:
3. Si pa owe si ọlọtẹ ilẹ na, si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Gbe ìkoko ka iná, gbe e kà a, si dà omi sinu rẹ̀ pẹlu:
4. Kó aján na jọ sinu rẹ̀, olukuluku aján ti o tobi, itan, ati apá, fi egungun ti o jọju kún inu rẹ̀.
5. Mu ninu agbo-ẹran ti o jọju, ko awọn egungun sabẹ rẹ̀, si jẹ ki o hó dãdã, si jẹ ki nwọn bọ̀ egungun rẹ̀ ninu rẹ̀.
6. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Egbé ni fun ilu ẹlẹjẹ na, fun ìkoko ti ifõfo rẹ̀ wà ninu rẹ̀, ti ifõfo rẹ̀ kò dá loju rẹ̀: mu u jade li aján li aján; máṣe dìbo nitori rẹ̀.
7. Nitori ẹjẹ rẹ̀ wà lãrin rẹ̀, o gbé e kà ori apata kan, kò tú u dà sori ilẹ, lati fi erupẹ bò o.
8. Ki o ba lè jẹ ki irúnu ki o de, lati gbẹsan; mo ti gbe ẹjẹ rẹ̀ kà ori apata kan, ki a má ba le bò o.