Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 22:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

2. Njẹ, iwọ ọmọ enia, iwọ o ha ṣe idajọ, iwọ o ha ṣe idajọ ilu ẹlẹjẹ na? nitõtọ, iwọ o jẹ ki o mọ̀ ohun irira rẹ̀ gbogbo.

3. Nitorina, iwọ wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Ilu ti o ta ẹjẹ silẹ lãrin rẹ̀, ki akoko rẹ̀ ki o le de, o si ṣe oriṣa si ara rẹ̀ lati sọ ara rẹ̀ di aimọ́.

4. Iwọ ti di ẹlẹbi niti ẹjẹ rẹ ti iwọ ti ta silẹ; iwọ si ti sọ ara rẹ di aimọ́ niti òriṣa rẹ ti iwọ ti ṣe, iwọ si ti mu ọjọ rẹ summọ tosí, iwọ si ti dé ọdun rẹ: nitorina ni mo ṣe sọ ọ di ẹgàn si awọn keferi, ati ẹsín si gbogbo ilẹ.

5. Awọn ti o sunmọ tosí, ati awọn ti o jìna si ọ, yio fi ọ ṣẹ̀sin, iwọ ti a bà orukọ rẹ̀ jẹ, ti a si bà ninu jẹ pupọ.

6. Kiyesi i, awọn ọmọ-alade Israeli, olukuluku ninu agbara rẹ̀ wà ninu rẹ lati ta ẹjẹ silẹ.

7. Ninu rẹ ni nwọn kò ka baba ati iyá si: lãrin rẹ ni nwọn ti ni awọn alejo lara: ninu rẹ ni nwọn ti bà alaini-baba ati opo ninu jẹ.

8. Iwọ ti gan awọn ohun mimọ́ mi, o si ti sọ ọjọ isimi mi di ailọ̀wọ.

9. Ninu rẹ ni awọn ọkunrin ti o nṣe ofófo lati ta ẹjẹ silẹ wà: ninu rẹ ni nwọn si jẹun lori awọn oke: lãrin rẹ ni nwọn huwà ifẹkufẹ.

10. Ninu rẹ ni nwọn ti tu ihòho baba wọn: ninu rẹ ni nwọn ti tẹ́ obinrin ti a yà sapakan nitori aimọ́ rẹ̀ logo.

11. Ẹnikan si ti ṣe ohun irira pẹlu aya aladugbo rẹ̀: ẹlomiran si ti fi ifẹkufẹ bà aya-ọmọ rẹ̀ jẹ́; ẹlomiran ninu rẹ si ti tẹ́ arabinrin rẹ̀ logo, ọmọ baba rẹ̀.

12. Ninu rẹ ni nwọn ti gba ẹbùn lati ta ẹjẹ silẹ: iwọ ti gba ẹdá ati elé, o si ti fi iwọra jère lara awọn aladugbo rẹ, nipa ilọni lọwọ-gbà; o si ti gbagbe mi, ni Oluwa, Ọlọrun wi.

Ka pipe ipin Esek 22