Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 20:12-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Pẹlupẹlu mo si fun wọn ni ọjọ isimi mi, lati ṣe àmi lãrin t'emi ti wọn, ki nwọn ki o le mọ̀ pe emi ni Oluwa ti o yà wọn si mimọ́.

13. Ṣugbọn ile Israeli ṣọ̀tẹ si mi ni aginjù: nwọn kò rìn ni aṣẹ mi, nwọn si gàn idajọ mi, eyiti bi enia kan ba ṣe, on o tilẹ yè ninu wọn; ati ọjọ isimi mi ni wọn tilẹ bajẹ gidigidi: nigbana ni mo wipe, emi o dà irúnu mi si wọn lori li aginju, lati pa wọn run.

14. Ṣugbọn mo ṣiṣẹ nitori orukọ mi, ki o má ba di ibajẹ niwaju awọn keferi, loju ẹniti mo mu wọn jade.

15. Pẹlupẹlu mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn ni aginju pe emi kò ni mu wọn de ilẹ ti mo ti fi fun wọn, ti nṣàn fun wàra ati fun oyin, ti iṣe ogo gbogbo ilẹ;

16. Nitoriti nwọn gàn idajọ mi, nwọn kò si rìn ninu aṣẹ mi, ṣugbọn nwọn bà ọjọ isimi mi jẹ: nitoripe ọkàn wọn tẹ̀le oriṣa wọn.

17. Ṣugbọn oju mi dá wọn si ki emi má ba pa wọn, bẹ̃ni emi kò ṣe wọn li aṣetan ni aginju.

18. Ṣugbọn mo sọ fun awọn ọmọ wọn li aginju pe, Ẹ máṣe rìn ninu aṣẹ baba nyin, ẹ má si ṣe kiyesi idajọ wọn, ẹ má si fi oriṣa wọn sọ ara nyin di aimọ́:

19. Emi ni Oluwa Ọlọrun nyin: ẹ rìn ninu aṣẹ mi, ẹ si pa idajọ mi mọ, ẹ si ṣe wọn;

20. Ẹ si bọ̀wọ fun ọjọ isimi mi; nwọn o si jẹ àmi lãrin t'emi ti nyin, ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi ni Oluwa Ọlọrun nyin.

21. Ṣugbọn awọn ọmọ na ṣọ̀tẹ si mi: nwọn kò rìn ninu aṣẹ mi, bẹ̃ni nwọn kò pa idajọ mi mọ lati ṣe wọn, eyiti bi enia kan ba ṣe, yio tilẹ yè ninu wọn; nwọn bà ọjọ isimi mi jẹ: mo si wipe, Emi o da irúnu mi sori wọn, lati pari ibinu mi sori wọn li aginju.

22. Ṣugbọn mo fà ọwọ́ mi sẹhìn, mo si ṣiṣẹ nitori orukọ mi, ki o má bà di ibajẹ li oju awọn keferi, loju ẹniti mo mu wọn jade.

23. Mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn pẹlu li aginju, lati tú wọn ka lãrin awọn keferi, ati lati fọ́n wọn ká ilẹ gbogbo;

24. Nitoripe nwọn kò mu idajọ mi ṣẹ, ṣugbọn nwọn kẹgàn aṣẹ mi, nwọn si ti bà ọjọ isimi mi jẹ, oju wọn si wà lara oriṣa baba wọn.

25. Nitorina mo fun wọn ni aṣẹ pẹlu ti kò dara, ati idajọ nipa eyiti wọn kì yio fi le yè;

26. Emi si bà wọn jẹ́ ninu ẹ̀bun ara wọn, nitipe nwọn mu gbogbo awọn akọbi kọja lãrin iná, ki emi ba le sọ wọn di ahoro, ki nwọn le bà mọ̀ pe emi ni Oluwa.

27. Nitorina, ọmọ enia, sọ fun ile Israeli, si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ninu eyi pẹlu baba nyin ti sọ̀rọ odi si mi, nitipe nwọn ti dẹṣẹ si mi.

28. Nitori nigbati mo ti mu wọn de ilẹ, niti eyiti mo gbé ọwọ́ mi soke lati fi i fun wọn, nigbana ni nwọn ri olukuluku oke giga, ati gbogbo igi bibò, nwọn si ru ẹbọ wọn nibẹ, nwọn si gbe imunibinu ọrẹ wọn kalẹ nibẹ: nibẹ pẹlu ni nwọn ṣe õrun didùn wọn, nwọn si ta ohun-ọrẹ mimu silẹ nibẹ.

Ka pipe ipin Esek 20