Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 14:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ọmọ enia, nigbati ilẹ na ba ṣẹ̀ si mi nipa irekọja buburu, nigbana ni emi o nawọ mi le e, emi o si ṣẹ́ ọpa onjẹ inu rẹ̀, emi o si rán ìyan si i, emi o si ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀:

14. Bi awọn ọkunrin mẹta wọnyi, Noa, Danieli, ati Jobu tilẹ wà ninu rẹ̀, kiki ẹmi ara wọn ni nwọn o fi ododo wọn gbàla, li Oluwa Ọlọrun wi.

15. Bi mo ba jẹ ki ẹranko buburu kọja lãrin ilẹ na, ti nwọn si bà a jẹ, tobẹ̃ ti o di ahoro, ti ẹnikan kò le là a ja nitori awọn ẹranko na.

16. Bi awọn ọkunrin mẹta wọnyi tilẹ wà ninu rẹ̀, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn kì yio gbà ọmọkunrin tabi ọmọbinrin là; awọn nikan li a o gbàla, ṣugbọn ilẹ na yio di ahoro.

17. Tabi bi mo mu idà wá sori ilẹ na, ti mo si wipe, Idà, la ilẹ na ja; tobẹ̃ ti mo ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀:

18. Bi awọn ọkunrin mẹta yi tilẹ wà ninu rẹ̀, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn kì yio gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin là, ṣugbọn awọn tikara wọn nikan li a o gbàla.

19. Tabi bi mo rán ajàkalẹ arùn si ilẹ na, ti mo si da irúnu mi le e ni ẹjẹ, lati ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀:

20. Bi Noa, Danieli, ati Jobu tilẹ wà ninu rẹ̀, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn kì yio gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin là; kìki ọkàn ara wọn ni awọn o fi ododo wọn gbàla.

21. Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Melomelo ni nigbati mo ba rán awọn idajọ kikan mi mẹrẹrin sori Jerusalemu, idà, ati iyàn, ati ẹranko buburu, ati ajakalẹ àrun, lati ké enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀?

22. Ṣugbọn kiye si i, ninu rẹ̀ li a o kù awọn ti a o yọ silẹ, ti a o mu jade wá, ati ọmọkunrin, ati ọmọbinrin, kiye si i, nwọn o jade tọ̀ nyin wá, ẹnyin o si ri ọ̀na wọn ati iṣe wọn, a o si tù nyin ninu niti ibi ti emi ti mu wá sori Jerusalemu, ani niti gbogbo ohun ti mo ti mu wá sori rẹ̀.

23. Nwọn o si tù nyin ninu, nigbati ẹnyin ba ri ọ̀na wọn ati iṣe wọn: ẹnyin o si mọ̀ pe emi kò ṣe gbogbo ohun ti mo ti ṣe ninu rẹ̀ li ainidi, ni Oluwa Ọlọrun wi.

Ka pipe ipin Esek 14