Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 14:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN kan ninu awọn àgba Israeli si wá sọdọ mi, nwọn si joko niwaju mi.

2. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

3. Ọmọ enia, awọn ọkunrin wọnyi ti gbe oriṣa wọn si ọkàn wọn, nwọn si fi ohun ìdigbolu aiṣedede wọn siwaju wọn: emi o ha jẹ ki nwọn bere lọwọ mi rara bi?

4. Nitorina sọ fun wọn, ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; olukuluku ọkunrin ile Israeli ti o gbe oriṣa rẹ̀ si ọkàn rẹ̀, ti o si fi ohun ìdugbolu aiṣedẽde rẹ̀ siwaju rẹ̀, ti o si wá sọdọ woli; emi Oluwa yio dá ẹniti o wá lohùn gẹgẹ bi ọpọlọpọ oriṣa rẹ̀.

5. Ki emi ba le mu ile Israeli li ọkàn ara wọn, nitori gbogbo wọn di ajeji si mi nipasẹ oriṣa wọn.

6. Nitorina wi fun ile Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹ ronupiwada, ki ẹ si yipada kuro lọdọ oriṣa nyin, ki ẹ si yi oju nyin kuro ninu ohun ẽri nyin.

7. Nitori olukuluku ninu ile Israeli, tabi ninu alejo ti o ṣe atipo ni Israeli, ti o yà ara rẹ̀ kuro lọdọ mi, ti o si gbe oriṣa rẹ̀ si ọkàn rẹ̀, ti o si fi ohun ìdugbolu aiṣedẽde rẹ̀ siwaju rẹ̀, ti o si tọ̀ wolĩ kan wá lati bere lọwọ rẹ̀ niti emi: Emi Oluwa yio da a lohùn tikalami:

Ka pipe ipin Esek 14