Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 13:15-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Bayi li emi o mu ibinu mi ṣẹ lori ogiri na, ati lori awọn ti o fi amọ̀ aipò rẹ ẹ, emi o si wi fun nyin pe, Ogiri na kò si mọ ati awọn ti o ti rẹ́ ẹ;

16. Eyini ni, awọn woli Israeli, ti nwọn sọtẹlẹ niti Jerusalemu, ti nwọn si ri iran alafia fun u, bẹ̃ni alafia kò si, ni Oluwa Ọlọrun wi.

17. Iwọ ọmọ enia, dojukọ awọn ọmọbinrin awọn enia rẹ bẹ̃ gẹgẹ, ti nwọn nsọtẹlẹ lati ọkàn ara wọn wá; ki o si sọtẹlẹ si wọn.

18. Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Egbé ni fun awọn obinrin ti nrán tìmtim si gbogbo ìgbọnwọ, ti nwọn sì ndá gèle si ori olukuluku enia lati ṣọdẹ ọkàn! Ẹnyin o ṣọdẹ ọkàn awọn enia mi bi, ẹnyin o si gbà ọkàn ti o tọ̀ nyin wá là bi?

19. Ẹnyin o ha si bà mi jẹ lãrin awọn enia mi nitori ikunwọ ọkà bàba, ati nitori òkele onjẹ, lati pa ọkàn ti kì ba kú, ati lati gba awọn ọkàn ti kì ba wà lãye là, nipa ṣiṣeke fun awọn enia mi ti ngbọ́ eke nyin?

20. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, mo dojukọ awọn tìmtim nyin, ti ẹnyin fi nṣọdẹ ọkàn nibẹ lati mu wọn fò, emi o si yà wọn kuro li apá nyin, emi o si jẹ ki awọn ọkàn na lọ, ani awọn ọkàn ti ẹnyin ndọdẹ lati mu fò.

21. Gèle nyin pẹlu li emi o ya, emi o si gba awọn enia mi lọwọ nyin, nwọn kì yio si si lọwọ nyin mọ lati ma dọdẹ wọn; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

22. Nitoripe eke li ẹnyin fi mu ọkàn awọn olododo kãnu, awọn ẹniti emi kò mu kãnu, ẹnyin si mu ọwọ́ enia buburu le, ki o má ba pada kuro li ọ̀na buburu rẹ̀ nipa ṣiṣe ileri ìye fun u:

Ka pipe ipin Esek 13