Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 12:20-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Awọn ilu ti a ngbe yio di ofo, ilẹ na yio si di ahoro; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

21. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

22. Ọmọ enia, owe wo li ẹnyin ni, ni ilẹ Israeli pe, A fà ọjọ gùn, gbogbo iran di asan?

23. Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o jẹ ki owe yi dẹkun, nwọn kì yio si pa a li owe ni Israeli mọ; ṣugbọn wi fun wọn pe, Ọjọ kù si dẹ̀dẹ; ati imuṣẹ gbogbo iran.

24. Nitori kì yio si iran asan mọ, kì yio si si afọṣẹ ti npọnni ninu ile Israeli.

25. Nitori emi li Oluwa: emi o sọ̀rọ, ọ̀rọ ti emi o sọ yio si ṣẹ, a kì yio fà a gùn mọ; nitori li ọjọ nyin, Ọlọtẹ ile, li emi o sọ ọ̀rọ na, emi o si ṣe e, ni Oluwa Ọlọrun wi.

26. Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe,

27. Ọmọ enia, kiyesi i, awọn ara ile Israeli wipe, Iran ti o ri, fun ọjọ pupọ ti mbọ̀ ni, o si sọ asọtẹlẹ akoko ti o jina rere.

28. Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Kò si ọkan ninu ọ̀rọ mi ti a o fà gùn mọ, ṣugbọn ọ̀rọ ti mo ti sọ yio ṣẹ, ni Oluwa wi.

Ka pipe ipin Esek 12