Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 12:12-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ọmọ-alade ti o wà larin wọn yio si rẹrù lori ejika rẹ̀ ni wiriwiri alẹ, yio si jade lọ; nwọn o si dá ogiri lu lati kó jade nibẹ; yio si bo oju rẹ̀, ki o má ba fi oju rẹ̀ ri ilẹ.

13. Awọ̀n mi ni emi o si tẹ́ le e lori, a o si mu u ninu ẹgẹ́ mi: emi o si mu u wá si Babiloni, si ilẹ awọn ara Kaldea; kì yio si ri i, bẹ̃ni yio kú nibẹ.

14. Gbogbo awọn ti o yi i ka lati ràn a lọwọ, ati gbogbo ọwọ-ogun rẹ̀, ni emi o tuká si gbogbo afẹ̃fẹ, emi o si yọ idà le wọn.

15. Nwọn o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa, nigbati mo ba tú wọn ka lãrin awọn orilẹ-ède; ti mo ba si fọ́n wọn ká ilẹ pupọ.

16. Ṣugbọn emi o kù diẹ ninu wọn silẹ lọwọ idà, lọwọ iyàn, ati lọwọ ajakálẹ arùn; ki nwọn le sọ gbogbo ohun ẽri wọn lãrin awọn keferi, nibiti nwọn ba de; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

17. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

18. Ọmọ enia, fi ìgbọnriri jẹ onjẹ rẹ, si fi ìwariri ati ikiyesara mu omi rẹ;

19. Ki o si sọ fun awọn enia ilẹ na pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn ara Jerusalemu, niti ilẹ Israeli; nwọn o fi ikiyesara jẹ onjẹ wọn, nwọn o si fi iyanu mu omi wọn, ki ilẹ rẹ̀ ki o le di ahoro kuro ninu gbogbo ohun ti o wà ninu rẹ̀, nitori ìwa-ipá gbogbo awọn ti ngbe ibẹ̀.

Ka pipe ipin Esek 12