Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 11:20-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Ki wọn le rìn ninu aṣẹ mi, ki wọn si le pa ilana mi mọ, ki nwọn si ṣe wọn: nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn.

21. Ṣugbọn bi o ṣe ti awọn ti ọkàn wọn nrìn nipa ọkàn ohun irira ati ohun ẽri wọn, Emi o sẹsan ọ̀na wọn sori ara wọn, li Oluwa Ọlọrun wi.

22. Awọn kerubu si gbe iyẹ́ wọn soke, pelu awọn kẹkẹ́ lẹgbẹ wọn, ogo Ọlọrun Israeli si wà lori wọn loke.

23. Ogo Oluwa si goke lọ kuro lãrin ilu na; o si duro lori oke-nla, ti o wà nihà ila-õrùn ilu na.

24. Lẹhin na ẹmi gbe mi soke, o si mu mi wá si Kaldea li ojuran, nipa Ẹmi Ọlọrun sọdọ awọn ti igbekun. Bẹ̃ni iran ti mo ti ri lọ kuro lọdọ mi.

25. Mo si sọ gbogbo ohun ti Oluwa ti fi hàn mi fun awọn ti igbekùn.

Ka pipe ipin Esek 11