Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 7:3-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Emi o si mu Farao li àiya le, emi o si sọ iṣẹ-àmi mi ati iṣẹ-iyanu mi di pupọ̀ ni ilẹ Egipti.

4. Ṣugbọn Farao ki yio gbọ́ ti nyin, emi o si fi ọwọ́ mi lé Egipti, emi o si fi idajọ nla mú awọn ogun mi, ani awọn ọmọ Israeli enia mi, jade kuro ni ilẹ Egipti.

5. Awọn ara Egipti yio si mọ̀ pe, emi li OLUWA, nigbati mo ba nà ọwọ́ mi lé Egipti, ti mo si mú awọn ọmọ Israeli jade kuro lãrin wọn.

6. Mose ati Aaroni si ṣe bẹ̃; bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn; bẹ̃ni nwọn ṣe.

7. Mose jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún, Aaroni si jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún o le mẹta, nigbati nwọn sọ̀rọ fun Farao.

8. OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,

9. Nigbati Farao yio ba wi fun nyin pe, Ẹ fi iṣẹ-iyanu kan hàn: nigbana ni ki iwọ ki o wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si fi i lelẹ niwaju Farao, yio si di ejò.

10. Mose ati Aaroni si wọle tọ̀ Farao lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn: Aaroni si fi ọpá rẹ̀ lelẹ niwaju Farao ati niwaju awọn iranṣẹ rẹ̀, o si di ejò.

11. Nigbana ni Farao pẹlu pè awọn ọlọgbọ́n ati awọn oṣó: awọn pẹlu, ani awọn alalupayida Egipti, si fi idán wọn ṣe bẹ̃ gẹgẹ.

Ka pipe ipin Eks 7