Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 7:10-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Mose ati Aaroni si wọle tọ̀ Farao lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn: Aaroni si fi ọpá rẹ̀ lelẹ niwaju Farao ati niwaju awọn iranṣẹ rẹ̀, o si di ejò.

11. Nigbana ni Farao pẹlu pè awọn ọlọgbọ́n ati awọn oṣó: awọn pẹlu, ani awọn alalupayida Egipti, si fi idán wọn ṣe bẹ̃ gẹgẹ.

12. Nitoriti olukuluku nwọn fi ọpá rẹ̀ lelẹ, nwọn si di ejò: ṣugbọn ọpá Aaroni gbe ọpá wọn mì.

13. Aiya Farao si le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.

14. OLUWA si wi fun Mose pe, Aiya Farao di lile, o kọ̀ lati jẹ ki awọn enia na ki o lọ.

15. Tọ̀ Farao lọ li owurọ̀; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki iwọ ki o si duro lati pade rẹ̀ leti odò; ati ọpá nì ti o di ejò ni ki iwọ ki o mú li ọwọ́ rẹ.

16. Iwọ o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu, li o rán mi si ọ wipe, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi ni ijù: si kiyesi i, titi di isisiyi iwọ kò gbọ́.

17. Bayi li OLUWA wi, Ninu eyi ni iwọ o fi mọ̀ pe emi li OLUWA: kiyesi i, emi o fi ọpá ti o wà li ọwọ́ mi lù omi ti o wà li odò, nwọn o si di ẹ̀jẹ.

18. Ẹja ti o wà ninu odò na yio si kú, odò na yio si ma rùn; awọn ara Egipti yio si korira ati ma mu ninu omi odò na.

19. OLUWA si sọ fun Mose pe, Wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si nà ọwọ́ rẹ si oju omi Egipti wọnni, si odò wọn, si omi ṣiṣàn wọn, ati ikudu wọn, ati si gbogbo ikojọpọ omi wọn, ki nwọn le di ẹ̀jẹ; ẹ̀jẹ yio si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, ati ninu ohun-èlo igi, ati ninu ohun-èlo okuta.

20. Mose ati Aaroni si ṣe bẹ̃ bi OLUWA ti fi aṣẹ fun wọn; o si gbé ọpá na soke o si lù omi ti o wà li odò li oju Farao, ati li oju awọn iranṣẹ rẹ̀; a si sọ gbogbo omi ti o wà li odò na di ẹ̀jẹ.

21. Ẹja ti o wà li odò si kú; odò na si nrùn, awọn ara Egipti kò si le mu ninu omi odò na; ẹ̀jẹ si wà ni gbogbo ilẹ Egipti,

22. Awọn alalupayida Egipti si fi idán wọn ṣe bẹ̃: àiya Farao si le, bẹ̃ni kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.

23. Farao si pada o lọ si ile rẹ̀, kò si fi ọkàn rẹ̀ si eyi pẹlu.

Ka pipe ipin Eks 7