Awọn enia na si gbàgbọ́: nigbati nwọn si gbọ́ pe, OLUWA ti bẹ̀ awọn ọmọ Israeli wò, ati pe o si ti ri ipọnju wọn, nigbana ni nwọn tẹ̀ ori wọn ba, nwọn si sìn.