Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 39:40-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

40. Aṣọ-tita agbalá na, ọwọ̀n rẹ̀ ati ihò-ìtẹbọ̀ rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na agbalá na, okùn rẹ̀, ati ekàn rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo ìsin agọ́ na, ani agọ́ ajọ;

41. Aṣọ ìsin lati ma fi sìn ninu ibi mimọ́, ati aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa.

42. Gẹgẹ bi gbogbo ohun ti OLUWA fi aṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe gbogbo iṣẹ na.

43. Mose si bojuwò gbogbo iṣẹ na, si kiyesi i, nwọn si ṣe e bi OLUWA ti palaṣẹ, bẹ̃ gẹgẹ ni nwọn ṣe e; Mose si sure fun wọn.

Ka pipe ipin Eks 39